Jóṣúà 14:6-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Àwọn ọkùnrin Júdà wá sí ọ̀dọ̀ Jósúà ní Gílígálì. Kálẹ́bù ọmọ Jéfúnè ti Kénísì wí fún un pé, “Ìwọ rántí ohun tí Olúwa sọ fún Mósè ènìyàn Ọlọ́run ní Kadesi-Báníyà nípa ìwọ àti èmi.

7. Mo jẹ́ ọmọ ogójì ọdún nígbà tí Mósè ìránṣẹ́ Olúwa rán mi láti Kádesi-Báníyà lọ rin ilẹ̀ náà wò. Mo sì mú ìròyìn wá fún un gẹ́gẹ́ bí o ti dá mi lójú,

8. ṣùgbọ́n àwọn arákùnrin mi tí wọ́n bá mi lọ mú àyà àwọn ènìyàn já. Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi fi gbogbo ọkàn tẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run mi.

9. Ní ọjọ́ náà, Mósè búra fún mi pé, ‘Ilẹ̀ tí ẹsẹ̀ rẹ ti rìn ni yóò jẹ́ ìní rẹ àti ti àwọn ọmọ rẹ láéláé, nítorí pé ìwọ fi tọkàntọkàn wà Pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run mi.’

10. “Bí Olúwa ti ṣe ìlérí, o ti mú mi wà láàyè fún ọdún márùn-úndínláàádọ́ta láti ìgbà tí ó ti sọ fún Mósè. Nígbà tí Ísírẹ́lì ń rìn kiri nínú aṣálẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi náà sì nìyí lónìí, ọmọ ọgọ́rin ọdún ó lé márùn-ún.

11. Síbẹ̀ èmi ní agbára lónìí, bí ìgbà tí Mósè rán mi jáde. Èmi sì ní agbára láti jáde fún ogun nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí mo ti wà ní ígbà náà.

Jóṣúà 14