Jóṣúà 13:21-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. gbogbo ìlú tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀e àti gbogbo agbégbé Síhónì ọba Ámórì, tí ó ṣe àkóso Héṣíbónì. Mósè sì ti sẹ́gun rẹ̀ àti àwọn ọmọ ìjòyè Mídíánì, Éfì, Rékémì, Súrì, Húrì àti Rébà, àwọn ọmọ ọba pàmọ̀pọ̀ pẹ̀lú Síhónì tí ó gbé ilẹ̀ náà.

22. Ní àfikún àwọn tí a pa ní ogun, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi idà pa Bálámù ọmọ Béórì alásọtẹ́lẹ̀.

23. Ààlà àwọn ọmọ Rúbẹ́nì ni etí odò Jọ́dánì. Àwọn ìlú wọ̀nyí àti abúlé rẹ̀ ni ilẹ̀ ìní àwọn ọmọ Rúbẹ́nì ní agbo ilé ní agbo ilé.

24. Èyí ni ohun tí Mósè ti fi fún ẹ̀yà Gádì, ní agbo ilé ní agbo ilé:

Jóṣúà 13