11. Àti Gílíádì, ní agbégbé àwọn ènìyàn Gésúrì àti Máákà, gbogbo Okè Hámónì àti gbogbo Básánì títí dé Sálẹ́kà,
12. Ìyẹn, gbogbo ilẹ̀ ọba Ógù ní Básánì, tí ó jọba ní Áṣítarótù àti Édérì, ẹni tí ó kù nínú àwọn Réfáítì ìyókù. Mósè ti ṣẹ́gun wọn, ó sì ti gba ilẹ̀ wọn.
13. Ṣùgbọ́n àwọn ará Ísírẹ́lì kò lé àwọn ará Géṣúrì àti Máákà jáde, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbé ní àárin àwọn ará Ísírẹ́lì títí di òní yìí.
14. Ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Léfì ni kò fi ogún kankan fún, níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ pé ọrẹ àfinásun sí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni ogún tiwọn, gẹ́gẹ́ bí o ti ṣèlérí fún wọn.
15. Èyí ni Mósè fi fún ẹ̀yà Rúbẹ́nì ni agbo ilé sí agbo ilé:
16. Láti agbégbé Áréórì ní etí Ánónì Jọ́ọ́jì àti láti ìlú tí ń bẹ láàrin Jọ́ọ́jì, àti gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ìkọjá Médébà
17. sí Héṣibónì àti gbogbo ìlú rẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú Débónì, Bámótì, Báálì, Bẹti-Báálì Míónì,
18. Jáhásì, Kédẹ́mótì, Méfáátì,
19. Kíríátaímù, Síbímà, Sẹrétì Sháárì lórí òkè ní àfonífojì.
20. Bẹti-Péórì, gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Písígà, àti Bẹti-Jésímátì
21. gbogbo ìlú tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀e àti gbogbo agbégbé Síhónì ọba Ámórì, tí ó ṣe àkóso Héṣíbónì. Mósè sì ti sẹ́gun rẹ̀ àti àwọn ọmọ ìjòyè Mídíánì, Éfì, Rékémì, Súrì, Húrì àti Rébà, àwọn ọmọ ọba pàmọ̀pọ̀ pẹ̀lú Síhónì tí ó gbé ilẹ̀ náà.
22. Ní àfikún àwọn tí a pa ní ogun, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi idà pa Bálámù ọmọ Béórì alásọtẹ́lẹ̀.