Jóṣúà 10:40-42 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

40. Bẹ́ẹ̀ ni Jóṣúà ṣẹ́gun gbogbo agbégbé náà, ìlú òkè, Négéfi, ìlú ẹsẹ̀ òkè ti ìhà ìwọ̀-óòrùn àti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè pẹ̀lú gbogbo ọba, wọn kò dá ẹnìkankan sí. Ó pa gbogbo ohun alààyè run pátapáta, gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ti pàṣẹ.

41. Jóṣúà sì ṣẹ́gun wọn láti Kadeṣi Báníyà sí Gásà àti láti gbogbo agbègbè Góṣénì lọ sí Gíbíónì.

42. Gbogbo àwọn ọba wọ̀nyí àti ilẹ̀ wọn ní Jósúà sẹ́gun ní ìwọ́de ogun ẹ́ẹ̀kan, nítorí tí Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, jà fún Ísírẹ́lì.

Jóṣúà 10