17. Gẹ́gẹ́ bí àwa ti gbọ́ran sí Móṣè nínú ohun gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni àwa yóò máa gbọ́ tìrẹ. Kí Olúwa Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lúù rẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà pẹ̀lú u Móṣè.
18. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tàpá sí ọ̀rọ̀ rẹ, tí kò sì ṣe ìgbọràn sí ọ̀rọ̀ rẹ, nínú ohun gbogbo tí ìwọ yóò paláṣẹ fún wọn, pípa ni a ó pa á. Kí ìwọ ṣáà ṣe gírí, kí ó sì mú àyà le!”