Jóòbù 39:25-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Ó wí nígbà ìpè pé, Háà! Háà!Ó sì gbóhùn ogun lókè réré, araàwọn balógun àti ariwo ogun wọn.

26. “Àwòdì ha máa ti ipa ọgbọ́n rẹ̀ fòsókè tí ó sì mọ ìyẹ́ apá rẹ̀ sí ìhà gúsù?

27. Idì ha máa fi àṣẹ rẹ̀ fò sókè kí ósì lọ tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí òkè gíga?

28. Ó ń gbé, ó sì ń wò ní orí àpáta,lórí pàlàpálá òkúta àti ibi orí òkè.

29. Láti ibẹ̀ lọ ni ó ti ń wá oúnjẹ́kiri, ojú rẹ̀ sì ríran rí òkè réré.

Jóòbù 39