Jóòbù 38:4-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. “Níbo ni ìwọ wà nígbà ti mo fiìpìnlẹ̀ ayé sọlẹ̀? Wí bí ìwọ bá mòye.

5. Ta ni ó fi ìwọ̀ rẹ lélẹ̀, dájú bí ìwọbá mọ̀ ọ́n? Tàbí ta ni ó ta okùn wíwọ̀n sórí rẹ?

6. Lórí ibo ni a gbé kan ìpìnlẹ̀ rẹ̀mọ́, tàbí ta ni ó fi òkúta igun rẹ̀ lélẹ̀,

7. Nígbà náà àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀jùmọ̀ Kọrin pọ̀, tí gbogbo àwọn áńgẹ́lì hó ìhó ayọ̀?

8. “Tàbí ta ni ó fi ìlẹ̀kùn sé omi òkunmọ́, nígbà tí ó ya padà bí ẹni pé ó ti inú jáde wá,

9. Nígbà tí mo fi àwọ sánmọ̀ ṣe aṣọrẹ̀, tí mo sì fi òkùnkùn biribiri se ọ̀já ìgbà nú rẹ̀,

Jóòbù 38