16. “Ìwọ ha wọ inú ìsun òkun lọ rí bí?Ìwọ sì rìn lórí ìsàlẹ̀ ibú ńlá?
17. A ha sílẹ̀kùn ikú sílẹ̀ fún ọ ríbí, ìwọ sì rí ilẹ̀kùn òjìji òkú?
18. Ìwọ mòye ibú ayé bí? Sọ bí ìwọbá mọ gbogbo èyí.
19. “Ọ̀nà wo ni ìmọ́lẹ̀ ń gbé? Bí óṣe ti òkùnkùn, níbo ni ipò rẹ̀,