Jóòbù 38:13-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Kí ó lè di òpin ilẹ̀ ayé mú, ki a lègbọ́n àwọn ènìyàn búburú kúrò nínú rẹ̀?

14. Kí ó yí padà bí amọ̀ fún èdìdìamọ̀, kí gbogbo rẹ̀ kí ó sì fi ara rẹ̀ hàn bí ẹni pé nínú aṣọ ìgúnwà.

15. A sì fa ìmọ́lẹ̀ wọn sẹ́yìn kúròlọ́dọ̀ ènìyàn búburú, apá gíga yóò sì ṣẹ́.

16. “Ìwọ ha wọ inú ìsun òkun lọ rí bí?Ìwọ sì rìn lórí ìsàlẹ̀ ibú ńlá?

Jóòbù 38