Jóòbù 34:4-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ẹ jẹ́ kí a ṣà ẹ̀tọ́ yàn fún ara wa;ẹ jẹ́ kí a mọ ohun tí ó dára láàrin wa.

5. “Nítorí pé Jóòbù wí pé, ‘Aláìlẹ́sẹ̀ ni èmi;Ọlọ́run sì ti gba ìdájọ́ mi lọ.

6. Èmi ha purọ́ sí ẹ̀tọ́ mi bí,bí mo tilẹ̀ jẹ́ aláìjẹ̀bi, ọfà rẹ̀ kò níàwòtán dídì ọgbẹ́.’

7. Ọkùnrin wo ni ó dàbí Jóòbù,tí ń mu ẹ̀gàn bí ẹní mú omi?

8. Tí ń bá àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kẹ́gbẹ́ tí ósì ń bá àwọn ènìyàn búburú rìn.

Jóòbù 34