Jóòbù 28:5-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Bí ó ṣe ti ilẹ̀ ni, nínú rẹ̀ ni oúnjẹ ti ń jáde wá,àti ohun tí ó wà ní ìṣàlẹ̀ ni ó yí sókè bí ẹni pé iná.

6. Òkúta ibẹ̀ ni ibi òkúta Sáfírì, o sìní erùpẹ̀ wúrà.

7. Ipa ọ̀nà náà ni ẹyẹ kò mọ̀, àti ojúgúnnugún kò rí i rí;

8. Àwọn ẹrankan agbéraga kò rìn ibẹ̀rí, bẹ́ẹ̀ ni kìnnìún tí ń ké ramúramù kò kọjá níbẹ̀ rí.

9. Ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé akọ òkúta, ó yí òkèńlá po láti ìdí rẹ̀ wá.

10. Ó sì la ipa odò ṣíṣàn nínú àpáta,ojú inú rẹ̀ sì rí ohun iyebíye gbogbo.

Jóòbù 28