6. Yóò ha fi agbára ńlá bá mi wíjọ́ bí?Àgbẹdọ̀, kìkì pé òun yóò sì kíyèsí mi.
7. Níbẹ̀ ni olódodo le è bá awíjọ́, níwájú rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni èmi yóòsì bọ́ ni ọwọ́ onídájọ́ mi láéláé.
8. “Sì wòó, bí èmi bá lọ sí iwájú,òun kò sí níbẹ̀, àti sí ẹ̀yìn, èmi kò sì rí òye rẹ̀:
9. Ni apá òsì bí ó bá ṣiṣẹ́ níbẹ̀, èmikò rí i, ó fi ara rẹ̀ pamọ́ ni apaọ̀tún, tí èmi kò le è rí i.
10. Ṣùgbọ́n òun mọ ọ̀nà tí èmi ń tọ̀,nígbà tí ó bá dán mí wò, èmi yóò jáde bí wúrà.
11. Ẹṣẹ̀ mí ti tẹ̀lé ipaṣẹ̀ ìrìn rẹ̀; ọ̀nàrẹ̀ ni mo ti kíyèsí, tí ń kò sì yà kúrò.