Jóòbù 20:5-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Pé, orin ayọ̀ ènìyàn búburú, ìgbàkúkúrú ni, àti pé, ní ìṣẹ́jú kan ní ayọ̀ àgàbàgebè?

6. Bí ọláńlá rẹ̀ tilẹ̀ gòkè dé ọ̀run, tiori rẹ̀ sì kan àwọsánmà;

7. Ṣùgbọ́n yóò ṣègbé láéláé bí ìgbẹ́ara rẹ̀; àwọn tí ó ti rí i rí yóò wí pé, ‘Òun ha dà?’

8. Yóò fò lọ bí àlá, a kì yóò sì rí i,àní a ó lé e lọ bi ìran òru.

Jóòbù 20