Jóòbù 18:8-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Nípa ẹ̀ṣẹ̀ òun tìkararẹ̀ ó ti bọ́ sínúàwọ̀n, ó sì rìn lóri okùn dídẹ.

9. Tàkúté ni yóò mú un ní gìgísẹ̀,àwọn àwọ̀n tí a dẹ yóò sì ṣẹ́gun rẹ̀.

10. A dẹkùn sílẹ̀ fún un lórí ilẹ̀, a sìwà ọ̀fìn fún un lojú ọ̀nà.

Jóòbù 18