Jóòbù 12:4-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. “Èmi dàbí ẹni tí a ń fi ṣe ẹlẹ́yà lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀,tí ó ké pe Ọlọ́run, tí ó sì dá a lóhùn:à ń fi olóòótọ́ ẹni-ìdúró-ṣinṣin rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà.

5. Ẹ̀gàn ni ẹni-ò-tòsì,tí ẹsẹ̀ rẹ múra tan láti yọ, nínú ìró ẹni tí ara rọ̀.

6. Àgọ́ àwọn ìgárá ń bẹ̀rù;àwọn tí ó sì ń mú Ọlọ́run bínú wà láìléwu,àwọn ẹni tí ó sì gbá òrìṣà mú ní ọwọ́ wọn.

7. “Ṣùgbọ́n nísínyìí bí àwọn ẹranko léèrè, wọn o kọ́ ọ ní ẹ̀kọ́,àti ẹyẹ ojú ọ̀run, wọn ó sì sọ fún ọ.

Jóòbù 12