Jòhánù 8:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisí sì mú obìnrin kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, tí a mú ní ṣíṣe panṣágà; wọ́n sì mú un dúró láàrin.

4. Wọ́n sì wí fún un pé, “Olùkọ́, a mú obìnrin yìí nínú ìṣe panṣágà,

5. Ǹjẹ́ nínú òfin, Mósè pàṣẹ fún wa láti sọ irú àwọn obìnrin bẹ́ẹ̀ ní òkúta, ṣùgbọ́n ìwọ ha ti wí?”

6. Èyí ni wọ́n wí, láti dán á wò, kí wọn ba à lè rí ẹ̀sùn kan kà sí i lọ́rùn.Ṣùgbọ́n Jésù bẹ̀rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ń fi ìka rẹ̀ kọ̀wé ní ilẹ̀.

Jòhánù 8