11. Jésù sì mú ìṣù àkàrà náà. Nígbà tí ó sì ti dúpẹ́, ó pín wọn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì pín wọn fún àwọn tí ó jókòó; bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sì ni ẹja ní ìwọn bí wọ́n ti ń fẹ́.
12. Nígbà tí wọ́n sì yó, ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ kó àjẹkù tí ó kù jọ, kí ohunkóhun má ṣe ṣòfò.”
13. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kó wọn jọ wọ́n sì fi àjẹkù ìṣù àkàrà barle márùn-ún náà kún agbọ̀n méjìlá, èyí tí àwọn tí ó jẹun jẹ kù.
14. Nítorí náà nígbà tí àwọn ọkùnrin náà rí iṣẹ́-àmì tí Jésù ṣe, wọ́n wí pé, “Lóòótọ́ èyí ni wòlíì náà tí ń bọ̀ wá sí ayé.”
15. Nígbà tí Jésù sì wòye pé wọ́n ń fẹ́ wá fi agbára mú òun láti lọ fi jọba, ó tún padà lọ sórí òkè, òun nìkan.
16. Nígbà tí alẹ́ sì lẹ́, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí òkun.
17. Wọ́n sì bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, wọ́n sì rékọjá òkun lọ sí Kápénámù. Ilẹ̀ sì ti ṣú, Jésù kò sì tí ì dé ọ̀dọ̀ wọn.