Jòhánù 5:37-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

37. Àti Baba tìkárarẹ̀ tí ó rán mi ti jẹ́rí mi. Ẹ̀yin kò gbọ́ ohùn rẹ̀ nígbà kan rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò rí ìrísí rẹ̀.

38. Ẹ kò sì ní ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti máa gbé inú yín: nítorí ẹni tí ó rán, òun ni ẹ̀yin kò gbàgbọ́.

39. Ẹ̀yin ń wá ìwé-mímọ́ nítorí ẹ̀yin rò pé nínú wọn ni ẹ̀yin ní ìyè tí kò nípẹ̀kun. Wọ̀nyí sì ni àwọn tí ó ń jẹ́rí mi.

Jòhánù 5