Jòhánù 11:26-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Ẹnikẹ́ni tí ó ń bẹ láàyè, tí ó sì gbà mí gbọ́, kì yóò kú láéláé ìwọ gbà èyí gbọ́?”

27. Ó wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa: èmi gbàgbọ́ pé, ìwọ ni Kírísítì náà Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí ń bọ̀ wá sí ayé.”

28. Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó lọ, ó sì pe Màríà arábìnrin rẹ̀ sẹ́yìn wí pé, “Olùkọ́ dé, ó sì ń pè ọ́.”

29. Nígbà tí ó gbọ́, ó dìde lọ́gán, ó sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀.

30. Jésù kò tíì wọ ìlú, ṣùgbọ́n ó wà ní ibi kan náà tí Màrta ti pàdé rẹ̀.

Jòhánù 11