Jòhánù 11:23-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Jésù wí fún un pé, “Arákùnrin rẹ yóò jíǹde.”

24. Màta wí fún un pé, “Mo mọ̀ pé yóò jíǹde ní àjíǹde ìkẹyìn.”

25. Jésù wí fún un pé, “Èmi ni àjíǹde àti ìyè: ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè:

26. Ẹnikẹ́ni tí ó ń bẹ láàyè, tí ó sì gbà mí gbọ́, kì yóò kú láéláé ìwọ gbà èyí gbọ́?”

Jòhánù 11