Jòhánù 10:37-42 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

37. Bí èmi kò bá ṣe iṣẹ́ Baba mi, ẹ má ṣe gbà mí gbọ́.

38. Ṣùgbọ́n bí èmi bá ṣe wọ́n, bí ẹ̀yin kò tilẹ̀ gbà mí gbọ́, ẹ gbà iṣẹ́ náà gbọ́: kí ẹ̀yin baà lè mọ̀, kí ó sì lè yé yín pé, Baba wà nínú mi, èmi sì wà nínú rẹ̀.”

39. Wọ́n sì tún ń wá ọ̀nà láti mú un: ó sì bọ́ lọ́wọ́ wọn.

40. Ó sì tún kọjá lọ sí apá kéjì Jodánì sí ibi tí Jòhánù ti kọ́kọ́ ń bamítísì; níbẹ̀ ni ó sì jókòó.

41. Àwọn ènìyàn púpọ̀ sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Jòhánù kò ṣe iṣẹ́ àmì kan: Ṣùgbọ́n òtítọ́ ni ohun gbogbo tí Jòhánù sọ nípa ti ọkùnrin yìí.”

42. Àwọn ènìyàn púpọ̀ níbẹ̀ sì gbàágbọ́.

Jòhánù 10