Jòhánù 1:47-50 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

47. Jésù rí Nàtaníẹ́lì ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí nípa rẹ̀ pé, “Èyí ni ọmọ Ísírẹ́lì tòótọ́, nínú ẹni tí ẹ̀tàn kò sí.”

48. Nàtaníẹ́lì béèrè pé, “Báwo ni ìwọ ti ṣe mọ̀ mí?”Jésù sì dáhùn pé, “Èmi rí ọ nígbà tí ìwọ wà lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ kí Fílípì tó pè ọ́.”

49. Nígbà náà ni Nàtaníẹ́lì sọ ọ́ gbangba pé, “Rábì, Ìwọ ni ọmọ Ọlọ́run; Ìwọ ni Ọba Ísírẹ́lì.”

50. Jésù sì wí fún un pé, “Ìwọ gbàgbọ́ nítorí mo wí fún ọ pé mo rí ọ lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́. Ìwọ ó rí ohun tí ó pọ̀ jù ìwọ̀nyí lọ.”

Jòhánù 1