Jóẹ́lì 3:18-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. “Ní ọjọ́ náà, àwọn òkè-ńlá yóò máa kán ọtí wáìnì tuntun sílẹ̀,àwọn òkè kéékèèkéé yóò máa ṣàn fún wàrà;gbogbo odò Júdà tí ó gbẹ́ yóò máa ṣàn fún omi.Oríṣun kan yóò sì ṣàn jáde láti inú ile Olúwa wá,yóò sì rin omi sí àfonífojì Ṣítímù.

19. Ṣùgbọ́n Éjíbítì yóò di ahoro,Édómù yóò sì di aṣálẹ̀ ahoro,nítorí ìwà ipá tí a hù sì àwọn ọmọ Júdà,ní ilẹ̀ ẹni tí wọ́n ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.

20. Ṣùgbọ́n Júdà yóò jẹ́ ibùgbé títí láé,àti Jérúsálẹ́mù láti ìran dé ìran.

21. Nítorí èmi yóò wẹ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wọn nù, tí èmi kò tíì wẹ̀nù.Nítorí Olúwa ń gbé Síónì.”

Jóẹ́lì 3