Jóẹ́lì 2:4-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ìrí wọn dàbí ìrí àwọn ẹṣin;wọ́n ń ṣe láńkú láńkú lọ bí àwọn ẹlẹ́ṣin ogun

5. Bí ariwo kẹ̀kẹ́ ogun niwọn ń fo ní orí òkèbí ariwo ọ̀wọ́ iná tí ń jó koríko gbígbẹ,bí akọni ènìyàn tí a kó jọ fún ogun.

6. Ní ojú wọn, àwọn ènìyàn yóò jẹ ìrora púpọ̀:gbogbo ojú ní yóò ṣú dudu.

7. Wọn yóò sáré bi àwọn alágbára;wọn yóò gùn odi bí ọkùnrin ológun;olúkúlúkù wọn yóò sì rìn lọ ní ọ̀nà rẹ̀,wọn kì yóò sì yà kúrò ni ọ̀nà wọn.

8. Bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì yóò to ẹnìkejì rẹ̀;olúkúlukù wọn yóò rìn ní ọ̀nà rẹ̀:nígbà tí wọn bá sì ṣubú lù ìdàwọn kì yóò gbọgbẹ́.

9. Wọn yóò sáré síwá ṣẹ́yìn ní ìlú;wọn yóò súré lórí odi,wọn yóò gùn orí ilé;wọn yóò gbà ojú fèrèsé wọ̀ inú ilé bí olè.

10. Ayé yóò mì níwájú wọn;àwọn ọ̀run yóò wárìrì;òòrùn àti òṣùpá yóò ṣókùnkùn,àwọn ìràwọ̀ yóò sì fà ìmọ́lẹ̀ wọn ṣẹ́yìn.

Jóẹ́lì 2