Jeremáyà 7:32-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

32. Nítorí náà kíyèsára ọjọ́-ń-bọ̀, ni Olúwa wí, nígbà tí àwọn ènìyàn kò ní pè é ní Táfétì tàbí àfonífojì ti Beni Hínómì; àfonífojì ìparun, nítorí wọn yóò sin òkú sí Tófẹ́tì títí kò fi ní sí àyè mọ́

33. Nígbà náà ni òkú àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀, kò sì ní sí ẹnìkan tí yóò dẹ́rùbà wọ́n.

34. Èmi yóò mú òpin bá ìró ayọ̀ àti ìdùnnú àti ohùn àwọn tọkọ tìyàwó ní àwọn ìlú Júdà àti ní ìgboro Jérúsálẹ́mù, nítorí tí ilẹ̀ náà yóò di ahoro.

Jeremáyà 7