Jeremáyà 6:16-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“Ẹ dúró sí ìkòríta, kí ẹ sì wò,ẹ bere fún ipa ìgbàanì, ẹ bèèrèọ̀nà dáradára nì, kí ẹ sì wọinú rẹ, ẹ̀yin yóò sì rí ìsinmifún ọkàn yín.Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa kì yóò rin nínú rẹ.’

17. Èmi yan olùsọ́ fún un yín,mo sì wí pé:‘Tẹ́tí sí dídún fèrè náà,’ẹ̀yìn wí pé, ‘Àwa kì yóò tẹ́tí sílẹ̀.’

18. Nítorí náà, gbọ́ ẹ̀yin orílẹ̀-èdèkíyèsí, kí ẹ sì jẹ́ ẹlẹ́rìíohun tí yóò sẹlẹ̀ sí wọn.

19. Gbọ́, ìwọ ayé! Mò ń múìparun bọ̀ sórí àwọn ènìyànwọ̀nyí, eṣo ìrò inú wọn, nítoríwọn kò fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, wọ́n sìti kọ òfin mi sílẹ̀.

Jeremáyà 6