4. “Ní ọjọ́ wọ̀nyí àti ní àkókò náà,”ni Olúwa wí,“Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò jùmọ̀ wá,àwọn, àti àwọn ọmọ Júdà,wọn yóò lọ pẹ̀lú ẹkún láti ṣàfẹ́ri Olúwa Ọlọ́run wọn
5. Wọn ó máa bèèrè ọ̀nà Síhónì, oju wọnyóò sì yí síhà ibẹ̀, wí pé ẹ wá, ẹ jẹ́ kí adarapọ̀ mọ́ Olúwa ní májẹ̀mú ayé-rayé,tí a kì yóò gbàgbé.
6. “Àwọn ènìyàn mi ti jẹ́ àgùntàn tí ó sọnù,àwọn olùṣọ́ àgùntàn wọn ti jẹ́ kí wọn sìnà,wọ́n ti jẹ́ kí wọn rìn lórí òkèwọ́n ti lọ láti orí òkè ńlá dé òkè kékeré,wọn ti gbàgbé ibùsùn wọn.