23. Wo bi ilé ayé ti pín sí wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ tó.Wo bí Bábílónì ti di aláìlólùgbéni àárin àwọn orílẹ̀ èdè.
24. Mo dẹ pàkúté sílẹ̀fún ọ ìwọ Bábílónì,kí o sì tó mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀,o ti kó sínú rẹ̀. A mú ọ nítorí pé o tako Olúwa.
25. Olúwa ti kó àwọn ohun èlòìjà rẹ̀ jáde, nítorí pé OlúwaỌlọ́run ọmọ ogun ti ṣiṣẹ́ ní ilẹ̀ Bábílónì.
26. Ẹ dìde sí láti ilẹ̀ jínjínpárun pátapáta láìṣẹ́kù.
27. Pa gbogbo àwọn ọ̀dọ́àgùntàn rẹ̀, jẹ́ kí a kówọn lọ ibi tí a ó ti pa wọ́n!Ègbé ní fún wọn! Nítorí ọjọ́ wọn dé,àkókò ìbẹ̀wò wọn.
28. Tẹ́tí sí àwọn tí ó sálọ tí ó sì sálà láti Bábílónì,sì sọ ní Síónì, bí Olúwa Ọlọ́run wa ti gbẹ̀san,ẹ̀san fún tẹ́ḿpílì rẹ̀.