Jeremáyà 42:20-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Pé àṣìṣe ńlá gbáà ni ẹ̀yin ṣe nígbà tí ẹ̀yin rán mi sí Olúwa Ọlọ́run yín pé, ‘Gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run wa fún wa; sọ fún wa gbogbo ohun tí ó bá sọ, àwa yóò sì ṣe é.’

21. Mo ti sọ fún un yín lónìí, ṣùgbọ́n síbẹ̀ ẹ̀yin kò tí ì gbọ́ ohùn Olúwa Ọlọ́run yín, àti gbogbo ohun tí ó rán mi láti sọ fún un yín.

22. Ǹjẹ́ nísinsìnyìí ẹ mọ èyí dájú pé: Ẹ̀yin yóò kú nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn níbikíbi tí ẹ̀yin bá fẹ́ lọ láti ṣe àtìpó.”

Jeremáyà 42