Jeremáyà 38:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Sefatíà ọmọ Mátanì, Gédáyà ọmọ Páṣúrì, Jéhúdù ọmọ Selemáyà àti Páṣúrì ọmọ Málíkíà gbọ́ ohun tí Jeremáyà ń sọ fún àwọn ènìyàn nígbà tí ó sọ wí pé,

2. “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Ẹnikẹ́ni tó bá dúró nínú ìlú yìí yóò kú nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn; ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tó bá lọ sí Bábílónì yóò yè; yóò sá àsálà, yóò sì yè.’

3. Àti pé èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Ìdánilójú wà wí pé a ó fi ìlú náà lé ọwọ́ àwọn ọmọ ogun Bábílónì; tí yóò sì kó wa nígbékùn.’ ”

Jeremáyà 38