14. Gbogbo àwọn ìjòyè sì rán Jéhúdù ọmọ Métamáyà ọmọ Sélémáyà ọmọ Kúsì sí Bárúkì wí pé, mú ìwé kíká náà ní ọwọ́ rẹ láti inú èyí tí ìwọ kà ní etí àwọn ènìyàn; kí o si wá. Nígbà náà ni Bárúkì ọmọ Nétayà wá sí ọ̀dọ̀ wọn pẹ̀lú ìwé kíká ní ọwọ́ rẹ̀.
15. Wọ́n sì wí fún pé, “Jòkòó, jọ̀wọ́ kà á sí etí wa!”Nígbà náà ni Bárúkì sì kàá ní etí wọn.
16. Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ náà tan; wọ́n ń wo ara wọn lójú pẹ̀lú ẹ̀rù. Wọ́n sì wí fún Bárúkì pé, “Àwa gbọdọ̀ jábọ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún Ọba.”
17. Wọ́n sì bèèrè lọ́wọ́ Bárúkì pé, “Sọ fún wa báwo ni o ṣe kọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí? Ṣé Jeremáyà ló sọ wọ́n?”
18. Bárúkì sì dá wọn lóhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, láti ẹnu rẹ̀ ni, ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ báyìí fún mi, èmi sì fi tàdáwà kọ wọ́n sínú ìwé náà.”
19. Nígbà náà ni àwọn ìjòyè sọ fún Bárúkì wí pé, “Lọ fi ara rẹ pamọ́ àti Jeremáyà, má sì ṣe jẹ́ kí ẹnìkan mọ ibi tí ẹ̀yin wà.”