Jeremáyà 32:19-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Títóbi ni iṣẹ́ rẹ, agbára sì ni ìṣe rẹ. Ojú rẹ sí sí gbogbo ọ̀nà àwọn ọkùnrin, ó sì fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí ìṣe àti ìwà rẹ̀.

20. O ṣe iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu ńlá ní Éjíbítì. O sì ń ṣe é títí di òní ní Ísírẹ́lì àti lára ọmọ ènìyàn tí ó sì ti gba òkìkí tí ó jẹ́ tìrẹ.

21. O kó àwọn Ísírẹ́lì ènìyàn rẹ jáde láti Éjíbítì pẹ̀lú àmì àti ìyanu nínú ọwọ́ agbára àti nína apá rẹ pẹ̀lú ẹ̀rù ńlá.

22. Ìwọ fún wọn nílẹ̀ yìí, èyí tí o ti ṣèlérí fún àwọn baba ńlá wọn; ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin.

Jeremáyà 32