Jeremáyà 28:14-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: mà á fi àjàgà onírin sí ọrùn gbogbo orílẹ̀ èdè láti lè máa sin Nebukadinésárì ti Bábílónì, àti pé gbogbo yín ni ẹ̀ ó máa sìn ín. Mà á tún fún un ní àṣẹ lórí àwọn ẹranko búburú.’ ”

15. Wòlíì Jeremáyà sọ fún Hananáyà wòlíì pé, “Tẹ́tí, Hananáyà! Olúwa ti rán ọ, síbẹ̀, o rọ orílẹ̀ èdè yìí láti gba irọ́ gbọ́.

16. Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Mo ṣetán láti mú ọ kúrò nínú ayé, ní ọdún yìí ni ìwọ yóò kú nítorí o ti wàásù ọ̀tẹ̀ sí Olúwa.’ ”

17. Ní oṣù keje ọdún yìí ni Hananáyà wòlíì kú.

Jeremáyà 28