Jeremáyà 27:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìṣèjọba Sedekáyà ọmọ Jòsáyà Ọba Júdà, ọ̀rọ̀ yìí tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa:

2. Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Ṣe ìjárá àti àjàgà fún ara rẹ, kí o sì fi wé ọrùn rẹ.

3. Kí o rán ọ̀rọ̀ sí Ọba ti Édómù, Móábù, Ámónì, Tírè àti Sídónì láti ọwọ́ àwọn ikọ̀ tí ó wá sí Jérúsálẹ́mù sọ́dọ̀ Sedekáyà Ọba Júdà.

4. Kí o sì pàṣẹ fún wọn láti wí fún àwọn olúwa wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: “Sọ èyí fún àwọn olúwa rẹ:

Jeremáyà 27