1. Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìṣèjọba Ọba Jehóáíkímù ọmọ Jòsáyà tí ń ṣe Ọba Júdà, ọ̀rọ̀ yìí wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa:
2. “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Dúró ní àgbàlà ilé Olúwa, kí o sì sọ fún gbogbo ènìyàn ilẹ̀ Júdà tí ó ti wá láti wá jọ́sìn ní ilé Olúwa: sọ gbogbo ohun tí mo paláṣẹ fún ọ; má ṣaláìsọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà.
3. Bóyá gbogbo wọn máa gbọ́ ọ̀rọ̀ náà tí ọ̀kọọkan wọn yóò kúrò nínú ìwà búburú wọn. Èmi ó yí ọkàn padà, n kò sì ní fi ibi tí mo ti rò sí wọn ṣe wọ́n.