8. Tí orílẹ̀ èdè ti mo kìlọ̀ fún bá yípadà kúrò nínú ìwà búburú wọn, nígbà náà ni Èmi yóò yí ọkàn mi padà níbi àjálù tí mo ti rò láti ṣe sí wọn.
9. Ní ìgbà mìíràn tí èmi bá tún kéde láti tẹ̀dó tàbí gbin orílẹ̀ èdè kan tàbí ìjọba kan.
10. Tí ó sì ṣe búburú ní ojú mi, tí kò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, nígbà náà ni èmi yóò tún ṣe rere tí mo ti fẹ́ ṣe fún wọn.
11. “Ǹjẹ́ nísìnsìnyìí, sọ fún àwọn ènìyàn Júdà àti àwọn olúgbé Jérúsálẹ́mù wí pé, ‘Báyìí ní Olúwa wí: Wò ó! Èmi ń gbérò ibi sí yin, èmi sì ń ṣe ìpinnu kan lórí yín. Nítorí náà ẹ yípadà kúrò lọ́nà búburú yín kí olúkúlúkù yín sì tún ọ̀nà àti ìṣe rè ṣe.’
12. Ṣùgbọ́n wọn yóò sọ wí pé, ‘Kò se nǹkànkan, àwa yóò tẹ̀ṣíwájú nínú èrò wa, ẹnìkọ̀ọkan wa, yóò tẹ̀lé agídí ọkàn búburú rẹ̀.’ ”