Jeremáyà 17:18-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Jẹ́ kí ojú ti àwọn ẹni tí ń lépa mi,ṣùgbọ́n pa mí mọ́ kúrò nínúìtìjú, jẹ́ kí wọn ó bẹ̀rù. Múọjọ́ ibi wá sórí wọn, fi ìparunìlọ́po méjì pa wọ́n run.

19. Èyí ni ohun tí Olúwa wí fún mi: “Lọ dúró ní ẹnu ọ̀nà àwọn ènìyàn níbi tí àwọn Ọba Júdà ń gbà wọlé tí wọ́n ń gbà jáde àti ní gbogbo ẹnu bodè Jérúsálẹ́mù.

20. Sọ fún wọ́n pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin Ọba Júdà àti gbogbo ẹ̀yin ènìyàn Júdà àti gbogbo ẹ̀yin tí ń gbé ní Jérúsálẹ́mù tí ń wọlé láti ẹnu-bodè yìí.

21. Báyìí ni Olúwa wí ẹ kíyèsi láti máa ru ẹrù lọ́jọ́ ìsinmi tàbí kí ẹ gbé wọlé láti ẹnu-bodè Jérúsálẹ́mù.

22. Má ṣe gbé ẹrù jáde kúrò nínú ilé yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe ṣe isẹ́kísẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ṣùgbọ́n kí ẹ pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ fún àwọn baba ńlá yín.

23. Ṣíbẹ̀ wọn kò gbọ́ tàbí tẹ́tí sílẹ̀, wọ́n jẹ́ Ọlọ́rùn líle; wọn kì í fẹ́ gbọ́ tàbí gba ìbáwí.

24. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá kíyèsí láti gbọ́ tèmi ní Olúwa wí, tí ẹ kò sì gbe ẹrù gba ti ẹnu bodè ìlú ní ọjọ́ ìsinmi, ṣùgbọ́n tí ẹ ya ọjọ́ ìsinmi, sí mímọ́, nípa pé ẹ kò ṣe iṣẹ́kísẹ́ ní ọjọ́ náà.

25. Nígbà náà ni Ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dáfídì yóò gba ti ẹnu-bodè wọlé pẹ̀lú àwọn ìjòyè rẹ̀. Àwọn àti ìjòyè wọn yóò gun ẹsin àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wá, àwọn ọkùnrin Júdà àti àwọn olùgbé Jérúsálẹ́mù yóò tẹ̀lé wọn; ìlú yìí yóò sì di ibi gbígbé títí láéláé.

Jeremáyà 17