Jeremáyà 13:2-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Bẹ́ẹ̀ ni mo ra àmùrè gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wí, mo sì dì í mọ́ ẹ̀gbẹ́ mi.

3. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá nígbà kejì:

4. Mú àmùrè tí o rà, kí o sì fi wé ẹ̀gbẹ́ rẹ, kí o sì lọ sí Pérátì kí o lọ pa á mọ́ sí pàlàpálá òkúta.

5. Nígbà náà ni mo lọ pa á mọ́ ní Pérátì gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wí fún mi.

Jeremáyà 13