7. Láti ìgbà tí mo ti mú àwọn baba yín jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wá títí di òní, mo kìlọ̀ fún wọn lọ́pọ̀ ìgbà wí pé, “Ẹ gbọ́ tèmi.”
8. Ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kọ bi ara sí i dípò èyí wọ́n tẹ̀ṣíwájú ni agídí ọkàn wọn. Mo sì mú gbogbo ègún inú májẹ̀mú tí mo ti ṣèlérí, tí mo sì ti pàṣẹ fún wọn láti tẹ̀lé, tí wọn kò tẹ̀lé.’ ”
9. Olúwa sì wí fún mi pé, “Ọ̀tẹ̀ kan wà láàrin àwọn ará Júdà àti àwọn tí ń gbé ní Jérúsálẹ́mù.
10. Wọ́n ti padà sí ìdí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wọn tí ó kọ̀ láti tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi, wọ́n ti tẹ̀lé àwọn Ọlọ́run mìíràn láti sìn wọ́n. Ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà ti fọ́ májẹ̀mú tí mo ṣe pẹ̀lú àwọn baba ńlá wọn.