Jeremáyà 11:2-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. “Fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí, kí o sì sọ wọ́n fún àwọn ènìyàn Júdà, àti gbogbo àwọn tó ń gbé ni Jérúsálẹ́mù.

3. Sọ fún wọn wí pé èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: ‘Ègbé ni fún ẹni náà tí kò pa ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí mọ́.

4. Àwọn májẹ̀mú tí mo pa láṣẹ fún àwọn baba ńlá yín, nígbà tí mo mú wọn jáde láti Éjíbítì, láti ìléru ìyọ́rin wá.’ Mo wí pé, ‘Ẹ gbọ́ tèmi, kí ẹ sì ṣe ohun gbogbo tí mo pa láṣẹ fún un yín. Ẹ̀yin ó sì jẹ́ ènìyàn mi: Èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run yín

Jeremáyà 11