21. Àwọn olùsọ́ àgùntàn jẹ́ aláìlóye, wọnkò sì wá Olúwa: nítorí náà wọn kì yóòṣe rere àti pé gbogbo agbo wọn ni yóò túká.
22. Fetísílẹ̀; ariwo ìdàrúdàpọ̀ ńlá náà ń bọ̀láti ilẹ̀ àríwá, yóò sì sọ ìlú Júdà diahoro àti ihò jàkùmọ̀
23. Èmi mọ̀ Olúwa wí pé ayé ènìyàn kì íṣe ti ara rẹ̀, kì í ṣe fún ènìyàn láti gbe igbésẹ ara rẹ̀.
24. Tún mi ṣe Olúwa, pẹ̀lú ìdájọ́ nìkankí o má sì ṣe é nínú ìbínú rẹ. Kí ìwọmá ṣe sọ mí di òfo.
25. Tú ìbínú rẹ síta sórí àwọn orílẹ̀ èdètí kò mọ̀ ọ́, sórí àwọn ènìyàntí wọn kò pe orúkọ rẹ. Nítorí péwọ́n ti jẹ Jákọ́bù run, wọ́n ti jẹ ẹ́run pátapáta, wọ́n sì ti ba ilẹ̀ ibùgbé rẹ̀ jẹ́.