Jẹ́nẹ́sísì 50:15-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Nígbà tí àwọn arákùnrin Jósẹ́fù rí i pé baba wọn kú, wọ́n wí fún ara wọn pé, “Ǹjẹ́ bí ó bá ṣe pé Jósẹ́fù sì fi wá sínú ńkọ́, tí ó sì fẹ́ gbẹ̀ṣan gbogbo aburú tí a ti ṣe sí i?”

16. Nítorí náà wọ́n ránṣẹ́ sí Jósẹ́fù wí pé, “Baba rẹ fi àṣẹ yìí sílẹ̀ kí ó tó lọ wí pé:

17. ‘Èyí ni kí ẹ̀yin kí ó sọ fún Jóṣẹ́fù: Mo bẹ̀ ọ́ kí o dáríjìn àwọn arákùnrin rẹ, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àti aburú tí wọ́n ṣe sí ọ, èyí tí ó mú ibi bá ọ’. Nísinsin yìí, jọ̀wọ́ dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run baba rẹ jìn wọ́n.” Nígbà tí iṣẹ́ ti wọ́n rán dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, Jósẹ́fù sunkún.

18. Àwọn arákùnrin rẹ̀ wá, wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n wí pé, “Ẹrú rẹ ni a jẹ́.”

Jẹ́nẹ́sísì 50