Jẹ́nẹ́sísì 5:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èyí ni àkọsílẹ̀ ìran Ádámù.Nígbà tí Ọlọ́run dá ènìyàn, ó dá a ní àwòrán Ọlọ́run.

2. Ó dá wọn ní akọ àti abo, ó sì súre fún wọn. Nígbà tí ó dá wọn tan ó pè wọ́n ní “ènìyàn.”

3. Nígbà tí Ádámù di ẹni Àádóje ọdún (130), ó bí ọmọkùnrin kan tí ó jọ ọ́, tí ó jẹ́ àwòrán ara rẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ṣétì.

4. Lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Ṣétì, ó tún wà láàyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún (800), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.

Jẹ́nẹ́sísì 5