Jẹ́nẹ́sísì 45:9-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Nísinsìn yìí, ẹ yára padà sọ́dọ̀ baba mi kí ẹ sì wí fun un pé, èyí ni ohun tí Jósẹ́fù ọmọ rẹ wí, Ọlọ́run ti fi mí ṣe àkóso fún gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì, ẹ sọ̀kalẹ̀ wá láì jáfara.

10. Ìwọ yóò gbé ní agbégbé Gósénì, ìwọ kì yóò jìnnà sí mi-ìwọ, àwọn ọmọ rẹ àti àwọn ọmọ-ọmọ rẹ, àwọn agbo ẹran rẹ àti agbo màlúù rẹ àti gbogbo ohun tí ìwọ ní.

11. Èmi yóò pèṣè fún yín níbẹ̀. Nítorí ó sì ku ọdún márùn ún gbáko ti ìyàn yóò fi mú. Kí ìwọ àti ilé rẹ àti ohun tí í ṣe tìrẹ má baà di aláìní.

12. “Ẹ̀yin fúnra yín àti Bẹ́ńjámínì arákùnrin mi pẹ̀lú rí i pé, lóòótọ́ lóòótọ́, èmi Jósẹ́fù ni mo ń bá a yín sọ̀rọ̀.

Jẹ́nẹ́sísì 45