Jẹ́nẹ́sísì 45:20-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Ẹ má ṣe àníyàn nípa ohun-ìní yín nítorí èyí tí ó dára jù nínú ilẹ̀ Éjíbítì yóò jẹ́ tiyín.’ ”

21. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe èyí. Jósẹ́fù fún wọn ni kẹ̀kẹ́ ẹrù bí Fáráò ti pàṣẹ, ó sì fún wọn ní oúnjẹ fún ìrìn-àjò wọn pẹ́lú.

22. Ó fún ẹni kọ̀ọ̀kan wọn ní aṣọ tuntun. Ṣùgbọ́n Bẹ́ńjámínì ni ó fún ní ọ̀ọ́dúnrún ẹyọ owó (300) idẹ fàdákà àti ìpààrọ̀ aṣọ márùn ún.

23. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó kó ránṣẹ́ sí baba rẹ̀: kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá tí ó ru àwọn ohun mèremère ilẹ̀ Éjíbítì àti abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá tí ó ru ọkà àti oríṣìíríṣìí oúnjẹ.

Jẹ́nẹ́sísì 45