Jẹ́nẹ́sísì 42:36-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

36. Jákọ́bù bàbá wọn wí fún wọn pé, “Ẹ ti mú mi pàdánù àwọn ọmọ mi. N kò rí Jósẹ́fù mọ́, bẹ́ẹ̀ ni n ò kò sì rí Símónì náà mọ. Ẹ sì tún fẹ́ mú Bẹ́ńjámínì lọ! Èmi ni gbogbo ohun búburú yìí wá ń ṣẹlẹ̀ sí.”

37. Nígbà náà ni Rúbẹ́nì wí fún bàbá rẹ̀ pé, “Pa àwọn ọmọ mi méjèèjì bí n kò bá mú Bẹ́ńjámínì padà wá fún ọ, èmi ni kí o fà á lé lọ́wọ́, n ó sì mu-un padà wá.”

38. Ṣùgbọ́n Jákọ́bù wí pé, “Ọmọ mi kì yóò bá a yín lọ, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nikan sì ni ó kù nínú àwọn ọmọ ìyá rẹ̀. Bí ohunkóhun bá sẹlẹ̀ sí i, ìbànújẹ́ ni yóò sì pa mi kú ni ọjọ́ ogbó mi yìí.”

Jẹ́nẹ́sísì 42