56. Nígbà tí ìyàn sì ti tàn ká gbogbo ilẹ̀ náà, Jósẹ́fù sí inú àká, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ta ọkà fún àwọn ènìyàn, nítorí ìyàn náà mú gan-an ní gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì.
57. Gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè sì ń wá láti ra oúnjẹ lọ́wọ́ Jósẹ́fù, nítorí ìyàn náà pọ̀ gidigidi káàkiri gbogbo ayé.