Jẹ́nẹ́sísì 40:9-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Olórí agbọ́tí sì ṣọ́ àlá rẹ̀ fún Jósẹ́fù, wí pé, “Ní ojú àlá mi, mo rí àjàrà kan (tí wọn ń fi èso rẹ̀ ṣe wáìnì) níwájú mi,

10. Mo sì rí ẹ̀ka mẹ́ta lórí àjàrà náà, ó yọ ẹ̀ka tuntun, ó sì tanná, láìpẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní í ní èso tí ó ti pọ́n.

11. Ife Fáráò sì wà lọ́wọ́ mi, mo sì mú àwọn èṣo àjàrà náà, mo sì fún un sínú ife Fáráò, mo sì gbé ife náà fún Fáráò.”

12. Jósẹ́fù wí fún-un pé, “Èyí ni ìtumọ̀ àlá rẹ. Ẹ̀ka mẹ́ta náà dúró fún ọjọ́ mẹ́ta.

Jẹ́nẹ́sísì 40