Jẹ́nẹ́sísì 4:24-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Bí a ó bá gbẹ̀san Káínì ní ìgbà méje,ǹjẹ́ kí a gba ti Lámékì nígbà àádọ́rin-lé-méje.”

25. Ádámù sì tún bá aya rẹ̀ lò pọ̀, ó sì bí ọmọkùnrin kan tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Ṣẹ́tì, tí ó túmọ̀ sí pé, “Ọlọ́run fún mi ní ọmọkùnrin mìíràn ní ipò Ábélì tí Káínì pa.”

26. Ṣẹ́tì náà sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Énọ́sì.Láti àkókò náà lọ ni àwọn ènìyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ké pe orúkọ Olúwa.

Jẹ́nẹ́sísì 4