17. Ọlọ́rún sì wí fún Ádámù pé, “Nítorí pé ìwọ fetí sí aya rẹ, ìwọ sì jẹ nínú èṣo igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀,’“Ègún ni fún ilẹ̀ nítorí rẹ;nínú ọ̀pọ̀ làálàá ni ìwọ yóò jẹ nínú rẹ̀,ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.
18. Ilẹ̀ yóò sì hu ẹ̀gún àti èsùsú fún ọ,ewéko igbó ni ìwọ yóò sì máa jẹ.
19. Nínú òógùn ojú rẹni ìwọ yóò máa jẹuntítí tí ìwọ yóò fi padà sí ilẹ̀,nítorí inú ilẹ̀ ni a ti mú ọ jáde wá;erùpẹ̀ ilẹ̀ ṣáà ni ìwọ,ìwọ yóò sì padà di erùpẹ̀.”
20. Ádámù sì sọ aya rẹ̀ ní Éfà nítorí òun ni yóò di ìyá gbogbo alààyè.
21. Olúwa sì dá ẹ̀wù awọ fún Ádámù àti aya rẹ̀, ó sì fi wọ̀ wọ́n.
22. Olúwa Ọlọ́run sì wí pé, “Ọkùnrin náà ti dàbí ọ̀kan lára wa, ó mọ rere àti búburú. A kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó na ọwọ́ rẹ̀ kí ó mú lára èṣo igi ìyè kí ó sì jẹ, kí ó sì wà láàyè títí láéláé.”